Leviticus 27:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ níti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún OLÚWA. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà.