Leviticus 27:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún OLÚWA: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́.