Leviticus 27:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.