Leviticus 27:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún OLÚWA. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n sètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n ómà èso bárílì.