Leviticus 27:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.