Leviticus 27:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátapáta láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí OLÚWA tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tàá kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún OLÚWA.