Leviticus 27:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó bá jẹ́ ọkunrin, tí ó jẹ́ ẹni ọdún marun-un sí ogun ọdún, yóo san ogun ìwọ̀n ṣekeli; bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ṣekeli mẹ́wàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin.