Leviticus 27:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún fún ọkunrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin.