Leviticus 27:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹni náà bá jẹ́ talaka tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè san iye tí ó yẹ kí ó san, mú ẹni tí ó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ alufaa kí alufaa díye lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ débi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá ṣíwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́.