Leviticus 4:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani gbogbo akọmalu na ni ki o mú jade lọ sẹhin ibudó si ibi mimọ́ kan, ni ibi ti a ndà ẽru si, ki o si fi iná sun u lori igi: ni ibi ti a ndà ẽru si ni ki a sun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọdi mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kó jọ.