Leviticus 4:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ti a fi oróro yàn ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na wá si agọ́ ajọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé.