Leviticus 4:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa na ki o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si wọ́n ọ nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú OLÚWA níbi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà.