Leviticus 4:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ti mbẹ ninu agọ́ ajọ, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú OLÚWA nínú àgọ́ ìpàdé. Ìyòókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.