Leviticus 4:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si fi akọmalu na ṣe; bi o ti fi akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ṣe, bẹ̃ni ki o si fi eyi ṣe: ki alufa na ki o si ṣètutu fun wọn, a o si dari rẹ̀ jì wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dárí jìn wọ́n.