Leviticus 4:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yóòkù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ