Leviticus 4:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.