Leviticus 4:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi alufa ti a fi oróro yàn ba ṣẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ awọn enia; nigbana ni ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan alailabùku fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí àlùfáà tí a fi òróró yàn bá ṣẹ̀, tí ó sì mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, ó gbọdọ̀ mú ọmọ akọ màlúù tí kò lábùkù wá fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.