Leviticus 4:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn si OLUWA; ki alufa na ki o si ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá ẹran náà gẹ́gẹ́ bó ṣe yọ ọ̀rá ẹran fún ọrẹ àlàáfíà. Kí àlùfáà sì sun ọ̀rá yìí lórí pẹpẹ bí òórùn dídùn sí OLÚWA. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, a ó sì dárí jìn-ín.