Leviticus 4:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá ọdọ-agutan kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA. Báyìí ni àlùfáà yóò se ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjìn-ín.