Leviticus 4:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa na ki o tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ na wọ́n nkan nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele ibi mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú OLÚWA, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́.