Leviticus 4:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lára ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ turari olóòórùn dídùn tí ó wà níwájú OLUWA, ninu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì da ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ turari didùn niwaju OLUWA, eyiti mbẹ ninu agọ́ ajọ; ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ akọmalu nì si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò tún mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tùràrí tó wà níwájú OLÚWA nínú àgọ́ ìpàdé. Kí ó da gbogbo ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù tókù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.