Leviticus 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn bí kò bá ní agbára láti mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji wá, ohun tí yóo mú wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni, ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ó má fi òróró tabi turari olóòórùn dídùn sórí rẹ̀, nítorí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbi ọmọ ẹyẹlẹ́ méjì wá, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.