Leviticus 5:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ OLÚWA, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtanràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni.