Leviticus 5:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ohun tí ó ti kùnà láti ṣe ní ti àwọn ohun mímọ́ OLÚWA, kí ó sì fi ìdá márùn-ún kún iye ohun tí ó kùnà láti ṣe nípa ohun mímọ́ OLÚWA kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà, ẹni tí yóò ṣe ètùtù fún un pẹ̀lú àgbò fún ẹbọ ẹ̀bi, a ó sì dárí jìn-ní.