Leviticus 5:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ó mú àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ alufaa, ó gbọdọ̀ rí i pé àgbò yìí tó iye tí wọn ń ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un fún àṣìṣe rẹ̀ tí ó ṣèèṣì ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mú àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá ni idiyele rẹ, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori aimọ̀ rẹ̀ ninu eyiti o ṣìṣe ti kò si mọ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dári jìn-ní.