Leviticus 5:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ẹnu ara rẹ̀ búra láìronú, kì báà jẹ́ láti ṣe ibi ni, tabi láti ṣe rere, irú ìbúra kíbùúra tí eniyan lè ṣe láìmọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀, ó di ẹlẹ́bi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yòówù tó ti búra láì kíyèsí ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi.