Leviticus 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ó sì mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ OLUWA fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Kí ó mú abo ọ̀dọ́ aguntan, tabi ti ewúrẹ́ wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.