Leviticus 5:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀-ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun.