Leviticus 6:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí OLÚWA.