Leviticus 6:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò gbọdọ̀ fi ìwúkàrà sí i, bí wọ́n bá fi ṣe burẹdi, èmi ni mo fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn ninu ẹbọ sísun mi; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ìmúkúrò ẹ̀bi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú yíìsìtì. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi! Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.