Leviticus 6:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọkunrin ninu àwọn ọmọ Aaroni lè jẹ ninu rẹ̀, èyí ni ìlànà mi títí ayérayé láàrin arọmọdọmọ yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ẹbọ wọnyi yóo di mímọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyíkéyí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Árónì ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.”