Leviticus 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ọrẹ tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún OLÚWA ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.