Leviticus 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí wọ́n fi òróró po ìyẹ̀fun náà dáradára, kí wọ́n tó yan án lórí ààrò, lẹ́yìn náà kí wọ́n rún un gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọ́n sì fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéé-kèè-kéé bí òórùn dídùn sí OLÚWA.