Leviticus 6:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí wọ́n bá yàn sí ipò olórí alufaa lẹ́yìn Aaroni ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo máa rú ẹbọ yìí sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí ìlànà títí lae, gbogbo ìyẹ̀fun náà ni yóo fi rú ẹbọ sísun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọkùnrin Árónì tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti OLÚWA títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátapáta.