Leviticus 6:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran fún ẹbọ sísun, ni kí wọ́n ti máa pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ pẹlu, níwájú OLUWA; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLÚWA níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.