Leviticus 6:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi ṣe ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi ṣe é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára.