Leviticus 7:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n bá jẹ ninu ẹran ẹbọ alaafia tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, ẹbọ náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ ẹni tí ó bá rú u, a kò ní kọ ọ́ sílẹ̀ fún un, nítorí pé ohun ìríra ni, ẹni tí ó bá jẹ ẹ́ ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ bá jẹ ọ̀kankan nínú ẹran ọrẹ àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta, kò ni jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. A kò ní í kà á sí fún ẹni tó rúbọ náà, nítorí pé ó jẹ́ àìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ ẹ́, ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù.