Leviticus 7:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ní àkókò tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọkàn na ti o ba jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ti on ti ohun aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí OLÚWA, a ó ge irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.