Leviticus 7:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ọkàn na ti o ba fọwọkàn ohun aimọ́ kan, bi aimọ́ enia, tabi ẹranko alaimọ́, tabi ohun irira elẽri, ti o si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti OLÚWA, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”