Leviticus 7:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún OLÚWA, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú OLÚWA bí ọrẹ fífí.