Leviticus 7:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Árónì àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Ísírẹ́lì.’ ”