Leviticus 8:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀meje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́,