Leviticus 8:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.