Leviticus 8:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.