Leviticus 8:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná se sí OLÚWA gẹ́gẹ́ bí OLÚWA tí pàṣẹ fún Mósè.