Leviticus 8:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.