Leviticus 8:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú OLÚWA àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.