Leviticus 8:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fìí níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.