Leviticus 8:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’