Leviticus 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí OLÚWA ti pá láṣẹ fún Mósè.